2 Ọba 19:24
2 Kings 19:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì, mo sì mu omi níbẹ̀. Pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi, èmi ti gbẹ́ gbogbo omi odò tí ó wà ní Ejibiti.”
2 Kings 19:24 in English
2 Kings 19:24 · Berean Standard Bible
I have dug wells and drunk foreign waters. With the soles of my feet I have dried up all the streams of Egypt.”
Context
22Ta ni ìwọ ti bú tí o sì kẹ́gàn rẹ̀?
Lórí ta ni ìwọ ti gbé ohùn rẹ
sókè tí ó sì gbé ojú sókè sí ọ ní ìgbéraga?
Lórí ẹni mímọ́ ti Israẹli! 23Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ
ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa.
Tì wọ sì wí pé,
“Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi
ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá,
sí ibi gíga jùlọ Lebanoni.
Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,
àti ààyò igi firi rẹ̀.
Èmi a sì lọ sí orí òkè ìbùwọ̀ rẹ̀
sínú ibi tí ó dára jù nínú igbó rẹ̀. 24Mo ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì,
mo sì mu omi níbẹ̀.
Pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi,
èmi ti gbẹ́ gbogbo omi odò tí ó wà ní Ejibiti.” 25“ ‘Ṣé ìwọ kò tí ì gbọ́?
Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn mo yàn án.
Ní ọjọ́ ogbó ni mo ṣètò rẹ̀;
nísinsin yìí mo ti mú wá sí ìkọjá
pé ìwọ ti yí ìlú olódi padà dí
òkìtì àlàpà òkúta. 26Àwọn ènìyàn wọn ń gbẹ nípa,
wọ́n ti dà á láàmú
wọ́n sì ti ṣọ́ di ìtìjú.
Wọ́n dàbí koríko igbó lórí pápá,
gẹ́gẹ́ bí ọkà tí ó rẹ̀ dànù kí ó tó dàgbàsókè,
gẹ́gẹ́ bí fífún ọkà tí ó hù jáde.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.