Native Bible

2 Kings 19:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ta ni ìwọ ti bú tí o sì kẹ́gàn rẹ̀? Lórí ta ni ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókè tí ó sì gbé ojú sókè sí ọ ní ìgbéraga? Lórí ẹni mímọ́ ti Israẹli!

2 Kings 19:22 in English

2 Kings 19:22 · Berean Standard Bible

Whom have you taunted and blasphemed? Against whom have you raised your voice and lifted your eyes in pride? Against the Holy One of Israel!

Context

20Nígbà náà Isaiah ọmọ Amosi rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ nípa ti Sennakeribu ọba Asiria. 21Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀, “ ‘Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni kẹ́gàn rẹ ó sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà. Ọmọbìnrin Jerusalẹmu mi orí sí ọ gẹ́gẹ́ bí o ti sálọ. 22Ta ni ìwọ ti bú tí o sì kẹ́gàn rẹ̀? Lórí ta ni ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókè tí ó sì gbé ojú sókè sí ọ ní ìgbéraga? Lórí ẹni mímọ́ ti Israẹli! 23Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa. Tì wọ sì wí pé, “Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá, sí ibi gíga jùlọ Lebanoni. Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀, àti ààyò igi firi rẹ̀. Èmi a sì lọ sí orí òkè ìbùwọ̀ rẹ̀ sínú ibi tí ó dára jù nínú igbó rẹ̀. 24Mo ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì, mo sì mu omi níbẹ̀. Pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi, èmi ti gbẹ́ gbogbo omi odò tí ó wà ní Ejibiti.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.