Native Bible

2 Kings 18:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wò ó, nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ejibiti, ẹ̀rún ọ̀pá pẹlẹbẹ ìyè fífọ́ yìí, èyí tí yóò wọ inú ọwọ́ ẹni tí ó sì bá fi ara tì í. Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ejibiti ṣe rí fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.

2 Kings 18:21 in English

2 Kings 18:21 · Berean Standard Bible

Look now, you are trusting in Egypt, that splintered reed of a staff that will pierce the hand of anyone who leans on it. Such is Pharaoh king of Egypt to all who trust in him.

Context

19Olùdarí pápá wí fún wọn pé, “Sọ fún Hesekiah pé, “ ‘Èyí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria sọ: Kí ni ìgbẹ́kẹ̀lé yìí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé? 20Ìwọ wí pé ìwọ ni ìmọ̀ àti agbára láti jagun, ṣùgbọ́n ìwọ sọ̀rọ̀ òfìfo lásán. Ǹjẹ́ ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé, tí ìwọ fi ń ṣe ọ̀tẹ̀ sí mi? 21Wò ó, nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ejibiti, ẹ̀rún ọ̀pá pẹlẹbẹ ìyè fífọ́ yìí, èyí tí yóò wọ inú ọwọ́ ẹni tí ó sì bá fi ara tì í. Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ejibiti ṣe rí fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ wọn lé e. 22Tí ìwọ bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀ wa lé Olúwa Ọlọ́run.” Òun ha kọ́ ní ẹnìkan náà tí ibi gíga àti àwọn pẹpẹ tí Hesekiah mú kúrò, tí ó wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, “O gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí ní Jerusalẹmu”? 23“ ‘Wá nísinsin yìí, ṣe àdéhùn pẹ̀lú ọ̀gá mi, ọba Asiria èmi yóò sì fún ọ ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin tí ìwọ bá lè kó àwọn tí yóò gùn ún sí orí rẹ!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.