2 Ọba 18:19
2 Kings 18:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olùdarí pápá wí fún wọn pé, “Sọ fún Hesekiah pé, “ ‘Èyí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria sọ: Kí ni ìgbẹ́kẹ̀lé yìí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé?
2 Kings 18:19 in English
2 Kings 18:19 · Berean Standard Bible
The Rabshakeh said to them, “Tell Hezekiah that this is what the great king, the king of Assyria, says: What is the basis of this confidence of yours?
Context
17Ọba Asiria rán alákòóso gíga jùlọ, ìjòyè pàtàkì àti àwọn adarí pápá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun tí ó pọ̀, láti Lakiṣi sí ọba Hesekiah ní Jerusalẹmu. Wọ́n wá sí òkè Jerusalẹmu wọ́n sì dúró ní etí ìdarí omi àbàtà òkè, ní ojú ọ̀nà tó lọ sí òpópó pápá alágbàfọ̀. 18Wọ́n sì pe ọba; àti Eliakimu ọmọ Hilkiah ẹni tí í ṣe ilé olùtọ́jú, Ṣebna akọ̀wé, àti Joah ọmọkùnrin Asafu tí ó jẹ́ akọ̀wé ìrántí jáde pẹ̀lú wọn. 19Olùdarí pápá wí fún wọn pé, “Sọ fún Hesekiah pé,
“ ‘Èyí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria sọ: Kí ni ìgbẹ́kẹ̀lé yìí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé? 20Ìwọ wí pé ìwọ ni ìmọ̀ àti agbára láti jagun, ṣùgbọ́n ìwọ sọ̀rọ̀ òfìfo lásán. Ǹjẹ́ ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé, tí ìwọ fi ń ṣe ọ̀tẹ̀ sí mi? 21Wò ó, nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ejibiti, ẹ̀rún ọ̀pá pẹlẹbẹ ìyè fífọ́ yìí, èyí tí yóò wọ inú ọwọ́ ẹni tí ó sì bá fi ara tì í. Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ejibiti ṣe rí fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.