2 Ọba 17:38
2 Kings 17:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú tí mo ti ṣe pẹ̀lú yín mọ́ àti kí ẹ má sin ọlọ́run mìíràn.
2 Kings 17:38 in English
2 Kings 17:38 · Berean Standard Bible
Do not forget the covenant I have made with you. Do not worship other gods,
Context
36Ṣùgbọ́n Olúwa, ẹni tí ó mú yín gòkè jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú agbára ńlá àti nínà apá, òun ni ẹni náà tí ó yẹ kí ẹ sìn. Òun ni ẹni tí ó yẹ kí ẹ tẹríba fún àti sí òun ni kí ẹ rú ẹbọ fún. 37Ó yẹ kí ẹ̀yin kí ó máa kíyèsi ara yín gidigidi láti pa ìlànà àti àṣẹ, àti òfin tí ó kọ fún un yín mọ́. Ẹ má ṣe sin ọlọ́run mìíràn. 38Ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú tí mo ti ṣe pẹ̀lú yín mọ́ àti kí ẹ má sin ọlọ́run mìíràn. 39Kúkú sin Olúwa Ọlọ́run rẹ; Òun ni ẹni náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá a yín.” 40Wọn kò ní gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ wọ́n ti àtijọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.