Native Bible

2 Kings 17:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọba Asiria mú àwọn ènìyàn láti Babeli, Kuta, Afa, Hamati àti Sefarfaimi, wọ́n sì fi wọ́n sínú ìlú Samaria láti rọ́pò àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n sì ń gbé ní ìlú náà.

2 Kings 17:24 in English

2 Kings 17:24 · Berean Standard Bible

Then the king of Assyria brought people from Babylon, Cuthah, Avva, Hamath, and Sepharvaim and settled them in the towns of Samaria to replace the Israelites. They took possession of Samaria and lived in its towns.

Context

22Àwọn ọmọ Israẹli forítì í nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu kò sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ wọn, 23títí tí Olúwa fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ wòlíì. Bẹ́ẹ̀ ni a kó gbogbo ènìyàn Israẹli kúrò ní ilẹ̀ wọn lọ sí ìgbèkùn ni Asiria, títí di òní yìí. 24Ọba Asiria mú àwọn ènìyàn láti Babeli, Kuta, Afa, Hamati àti Sefarfaimi, wọ́n sì fi wọ́n sínú ìlú Samaria láti rọ́pò àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n sì ń gbé ní ìlú náà. 25Nígbà tí wọ́n gbé bẹ̀ ní àkọ́kọ́, wọn kò sì bẹ̀rù Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni ó rán kìnnìún sí àárín wọn. Wọ́n sì pa nínú wọn. 26Wọ́n sì sọ fún ọba Asiria pé, “Àwọn ènìyàn tí ìwọ lé kúrò tí o sì fi sínú ìlú Samaria kò mọ ohun tí ọlọ́run ìlú náà béèrè. Ó sì ti rán kìnnìún sí àárín wọn, tí ó sì ń pa wọ́n run, nítorí ènìyàn wọn kò mọ ohun tí ó béèrè.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.