2 Ọba 17:22
2 Kings 17:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọmọ Israẹli forítì í nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu kò sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ wọn,
2 Kings 17:22 in English
2 Kings 17:22 · Berean Standard Bible
The Israelites persisted in all the sins that Jeroboam had committed and did not turn away from them.
Context
20Nítorí náà Olúwa kọ gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli; ó sì jẹ wọ́n ní yà. Ó sì fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn olè títí tí ó fi ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀. 21Nígbà tí ó ta Israẹli kúrò láti ìdílé Dafidi, wọ́n sì mú Jeroboamu ọmọ Nebati jẹ ọba wọn. Jeroboamu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli yípadà kúrò ní títẹ̀lé Olúwa, ó sí mú kí wọn dẹ́ṣẹ̀ ńlá. 22Àwọn ọmọ Israẹli forítì í nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu kò sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ wọn, 23títí tí Olúwa fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ wòlíì. Bẹ́ẹ̀ ni a kó gbogbo ènìyàn Israẹli kúrò ní ilẹ̀ wọn lọ sí ìgbèkùn ni Asiria, títí di òní yìí. 24Ọba Asiria mú àwọn ènìyàn láti Babeli, Kuta, Afa, Hamati àti Sefarfaimi, wọ́n sì fi wọ́n sínú ìlú Samaria láti rọ́pò àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n sì ń gbé ní ìlú náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.