2 Ọba 17:12
2 Kings 17:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sìn òrìṣà, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí.”
2 Kings 17:12 in English
2 Kings 17:12 · Berean Standard Bible
They served idols, although the LORD had told them, “You shall not do this thing.”*
Context
10Wọ́n sì gbé àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ̀ sókè àti ère òrìṣà Aṣerah lórí gbogbo igi tútù. 11Ní gbogbo ibi gíga, wọ́n sun tùràrí gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú wọn. Wọ́n ṣe ohun búburú tí ó rú ìbínú Olúwa sókè. 12Wọ́n sìn òrìṣà, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí.” 13Olúwa kìlọ̀ fún Israẹli àti Juda nípa gbogbo àwọn wòlíì wọn àti aríran: “Ẹ yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú yín. Kí ẹ ṣe òfin mi àti ìlànà mi, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin tí Èmi paláṣẹ fún àwọn baba yín láti tẹ̀lé àti èyí tí mo rán sí i yín nípa ìránṣẹ́ àwọn wòlíì mi.” 14Ṣùgbọ́n wọn kò ní gbọ́, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́rùn líle gẹ́gẹ́ bí i ti baba wọn, ẹni tí kò gbà Olúwa Ọlọ́run wọn gbọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.