Native Bible

2 Kings 16:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Resini ọba Siria àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá sí Jerusalẹmu láti jagun: wọ́n dó ti Ahasi, ṣùgbọ́n wọn kò lè borí rẹ̀.

2 Kings 16:5 in English

2 Kings 16:5 · Berean Standard Bible

Then Rezin king of Aram and Pekah son of Remaliah king of Israel came up to wage war against Jerusalem. They besieged Ahaz but could not overcome him.

Context

3Ṣùgbọ́n ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli, nítòótọ́, ó sì sun ọmọ rẹ̀ nínú iná, gẹ́gẹ́ bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 4Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní àwọn ibi gíga, àti lórí àwọn òkè kéékèèké àti lábẹ́ gbogbo igi tútù. 5Nígbà náà ni Resini ọba Siria àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá sí Jerusalẹmu láti jagun: wọ́n dó ti Ahasi, ṣùgbọ́n wọn kò lè borí rẹ̀. 6Ní àkókò náà, Resini ọba Siria gba Elati padà fún Siria, ó sì lé àwọn ènìyàn Juda kúrò ní Elati: àwọn ará Siria sì wá sí Elati, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí. 7Ahasi sì rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ Tiglat-Pileseri ọba Asiria wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni èmi, àti ọmọ rẹ; gòkè wá, kí o sì gbà mi lọ́wọ́ ọba Siria, àti lọ́wọ́ ọba Israẹli tí ó dìde sí mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.