Native Bible

2 Kings 16:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní àwọn ibi gíga, àti lórí àwọn òkè kéékèèké àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.

2 Kings 16:4 in English

2 Kings 16:4 · Berean Standard Bible

And he sacrificed and burned incense on the high places, on the hills, and under every green tree.

Context

2Ẹni ogún ọdún ni Ahasi nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ọdún mẹ́rìndínlógún ní Jerusalẹmu, kò sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ̀. 3Ṣùgbọ́n ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli, nítòótọ́, ó sì sun ọmọ rẹ̀ nínú iná, gẹ́gẹ́ bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 4Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní àwọn ibi gíga, àti lórí àwọn òkè kéékèèké àti lábẹ́ gbogbo igi tútù. 5Nígbà náà ni Resini ọba Siria àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá sí Jerusalẹmu láti jagun: wọ́n dó ti Ahasi, ṣùgbọ́n wọn kò lè borí rẹ̀. 6Ní àkókò náà, Resini ọba Siria gba Elati padà fún Siria, ó sì lé àwọn ènìyàn Juda kúrò ní Elati: àwọn ará Siria sì wá sí Elati, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.