Native Bible

2 Kings 14:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa ti rí ìpọ́njú Israẹli pé, ó korò gidigidi, nítorí kò sí ẹrú tàbí òmìnira tàbí olùrànlọ́wọ́ kan fún Israẹli.

2 Kings 14:26 in English

2 Kings 14:26 · Berean Standard Bible

For the LORD saw that the affliction of the Israelites, both slave and free, was very bitter. There was no one to help Israel,

Context

24Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati. Èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá. 25Òun ni ẹni tí ó ti dá àwọn ààlà Israẹli padà láti Lebo-Hamati sí òkú aginjù. Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ Jona ọmọ Amittai, wòlíì láti Gati-Heferi. 26Olúwa ti rí ìpọ́njú Israẹli pé, ó korò gidigidi, nítorí kò sí ẹrú tàbí òmìnira tàbí olùrànlọ́wọ́ kan fún Israẹli. 27Láti ìgbà tí Olúwa kò ti wí pé òhun yóò bu àbùkù lu orúkọ Israẹli láti abẹ́ ọ̀run. Ó gbà wọ́n là, lọ́wọ́ Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi. 28Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jeroboamu, gbogbo ohun tí ó ṣe àti gbogbo àwọn agbára rẹ, bí ó ti jagun sí, àti bí ó ti gba Damasku àti Hamati, tí í ṣe ti Juda, padà fún Israẹli, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.