2 Ọba 14:25
2 Kings 14:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun ni ẹni tí ó ti dá àwọn ààlà Israẹli padà láti Lebo-Hamati sí òkú aginjù. Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ Jona ọmọ Amittai, wòlíì láti Gati-Heferi.
2 Kings 14:25 in English
2 Kings 14:25 · Berean Standard Bible
This Jeroboam restored the boundary of Israel from Lebo-hamath to the Sea of the Arabah,* according to the word that the LORD, the God of Israel, had spoken through His servant Jonah son of Amittai, the prophet from Gath-hepher.
Context
23Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún tí Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda, Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ọba Israẹli di ọba ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún ọ̀kànlélógójì ọdún. 24Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati. Èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá. 25Òun ni ẹni tí ó ti dá àwọn ààlà Israẹli padà láti Lebo-Hamati sí òkú aginjù. Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ Jona ọmọ Amittai, wòlíì láti Gati-Heferi. 26Olúwa ti rí ìpọ́njú Israẹli pé, ó korò gidigidi, nítorí kò sí ẹrú tàbí òmìnira tàbí olùrànlọ́wọ́ kan fún Israẹli. 27Láti ìgbà tí Olúwa kò ti wí pé òhun yóò bu àbùkù lu orúkọ Israẹli láti abẹ́ ọ̀run. Ó gbà wọ́n là, lọ́wọ́ Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.