2 Ọba 14:22
2 Kings 14:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun ni ẹni tí ó tún Elati kọ́, ó sì dá a padà sí Juda lẹ́yìn tí Amasiah ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀.
2 Kings 14:22 in English
2 Kings 14:22 · Berean Standard Bible
Azariah was the one who rebuilt Elath * and restored it to Judah after King Amaziah rested with his fathers.
Context
20Wọ́n gbé e padà pẹ̀lú ẹṣin, a sì sin ín sí Jerusalẹmu pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, ní ìlú ńlá ti Dafidi. 21Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn Juda mú Asariah tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún. Wọ́n sì ṣe é ní ọba ní ìrọ́pò baba rẹ̀ Amasiah. 22Òun ni ẹni tí ó tún Elati kọ́, ó sì dá a padà sí Juda lẹ́yìn tí Amasiah ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. 23Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún tí Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda, Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ọba Israẹli di ọba ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún ọ̀kànlélógójì ọdún. 24Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati. Èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.