2 Ọba 14:15
2 Kings 14:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jehoaṣi, gbogbo ohun tí ó ṣe pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀, pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Amasiah ọba Juda, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?
2 Kings 14:15 in English
2 Kings 14:15 · Berean Standard Bible
As for the rest of the acts of Jehoash, along with his accomplishments, his might, and how he waged war against Amaziah king of Judah, are they not written in the Book of the Chronicles of the Kings of Israel?
Context
13Jehoaṣi ọba Israẹli fi agbára mú Amasiah ọba Juda, ọmọ Jehoaṣi, ọmọ Ahasiah ní Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà, Jehoaṣi lọ sí Jerusalẹmu, ó sì lọ wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀ láti ìlẹ̀kùn Efraimu sí ibi igun ìlẹ̀kùn. Ìpín kan tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ irinwó (400) ìgbọ̀nwọ́. 14Ó mú gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun tí ó rí nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti níbi ìfowópamọ́ sí nínú ààfin ọba. Ó mú àwọn ògo, ó sì dá wọn padà sí Samaria. 15Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jehoaṣi, gbogbo ohun tí ó ṣe pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀, pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Amasiah ọba Juda, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli? 16Jehoaṣi sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín sí Samaria pẹ̀lú àwọn ọba Israẹli. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 17Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.