Native Bible

2 Kings 13:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ènìyàn Ọlọ́run sì bínú sí i, ó sì wí pé, “Ìwọ kò bá ti lu ilẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀márùn ún tàbí ní ẹ̀ẹ̀mẹ́fà, nígbà náà, ìwọ kò bá ti ṣẹ́gun Siria àti pa á run pátápátá ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ yóò ṣẹ́gun rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta péré.”

2 Kings 13:19 in English

2 Kings 13:19 · Berean Standard Bible

But the man of God was angry with him and said, “You should have struck the ground five or six times. Then you would have struck down Aram until you had put an end to it. But now you will strike down Aram only three times.”

Context

17“Ṣí fèrèsé apá ìlà-oòrùn,” ó wí, pẹ̀lú ó sì ṣí i: “Ta á!” Eliṣa wí, ó sì ta á. “Ọfà ìṣẹ́gun Olúwa; ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria!” Eliṣa kéde. “Ìwọ yóò pa àwọn ará Siria run pátápátá ní Afeki.” 18Nígbà náà ó wí pé, “Mú àwọn ọfà náà,” ọba sì mú wọn. Eliṣa wí fún un pé, “Lu ilẹ̀.” Ó lù ú lẹ́ẹ̀mẹ́ta, ó sì dáwọ́ dúró. 19Ènìyàn Ọlọ́run sì bínú sí i, ó sì wí pé, “Ìwọ kò bá ti lu ilẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀márùn ún tàbí ní ẹ̀ẹ̀mẹ́fà, nígbà náà, ìwọ kò bá ti ṣẹ́gun Siria àti pa á run pátápátá ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ yóò ṣẹ́gun rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta péré.” 20Eliṣa kú a sì sin ín. Ẹgbẹ́ àwọn ará Moabu máa ń wọ orílẹ̀-èdè ní gbogbo àmọ́dún. 21Bí àwọn ọmọ Israẹli kan ti ń sin òkú ọkùnrin kan, lójijì wọ́n rí ẹgbẹ́ àwọn oníjadì, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Eliṣa. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan egungun Eliṣa, ó padà wá sí ayé, ó sì dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.