2 Ọba 13:17
2 Kings 13:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ṣí fèrèsé apá ìlà-oòrùn,” ó wí, pẹ̀lú ó sì ṣí i: “Ta á!” Eliṣa wí, ó sì ta á. “Ọfà ìṣẹ́gun Olúwa; ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria!” Eliṣa kéde. “Ìwọ yóò pa àwọn ará Siria run pátápátá ní Afeki.”
2 Kings 13:17 in English
2 Kings 13:17 · Berean Standard Bible
“Open the east window,” said Elisha. So he opened it and Elisha said, “Shoot!” So he shot. And Elisha declared: “This is the LORD’s arrow of victory, the arrow of victory over Aram, for you shall strike the Arameans in Aphek until you have put an end to them.”
Context
15Eliṣa wí pé, “Mú ọrun kan àti àwọn ọfà,” ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. 16“Mú ọrun ní ọwọ́ rẹ.” Ó wí fún ọba Israẹli. Nígbà tí ó ti mú u, Eliṣa mú ọwọ́ rẹ̀ lé ọwọ́ ọba. 17“Ṣí fèrèsé apá ìlà-oòrùn,” ó wí, pẹ̀lú ó sì ṣí i: “Ta á!” Eliṣa wí, ó sì ta á. “Ọfà ìṣẹ́gun Olúwa; ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria!” Eliṣa kéde. “Ìwọ yóò pa àwọn ará Siria run pátápátá ní Afeki.” 18Nígbà náà ó wí pé, “Mú àwọn ọfà náà,” ọba sì mú wọn. Eliṣa wí fún un pé, “Lu ilẹ̀.” Ó lù ú lẹ́ẹ̀mẹ́ta, ó sì dáwọ́ dúró. 19Ènìyàn Ọlọ́run sì bínú sí i, ó sì wí pé, “Ìwọ kò bá ti lu ilẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀márùn ún tàbí ní ẹ̀ẹ̀mẹ́fà, nígbà náà, ìwọ kò bá ti ṣẹ́gun Siria àti pa á run pátápátá ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ yóò ṣẹ́gun rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta péré.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.