Native Bible

2 Kings 12:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹtàlélógún ọba Jehoaṣi, àwọn àlùfáà kò ì tí ì tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.

2 Kings 12:6 in English

2 Kings 12:6 · Berean Standard Bible

By the twenty-third year of the reign of Joash, however, the priests had not yet repaired the damage to the temple.

Context

4Jehoaṣi sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Gba gbogbo owó tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ mímọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa owó tí a gbà ní ìgbà kíka àwọn ènìyàn ìlú, owó tí a gbà láti ọwọ́ olúkúlùkù bí wọ́n ti ṣe jẹ́ ẹ̀yà àti owó tí ó ti ọkàn olúkúlùkù wá tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. 5Jẹ́ kí gbogbo àlùfáà gba owó náà lọ́wọ́ ọ̀kan nínú àwọn akápò. Kí a sì lò ó fún tuntun ohunkóhun tí ó bá bàjẹ́ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.” 6Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹtàlélógún ọba Jehoaṣi, àwọn àlùfáà kò ì tí ì tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe. 7Nígbà náà, ọba Jehoaṣi pe Jehoiada àlùfáà àti àwọn àlùfáà yòókù, ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tún ìbàjẹ́ tí a ṣe sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe? Ẹ má ṣe gba owó mọ́ lọ́wọ́ àwọn afowópamọ́, ṣùgbọ́n ẹ gbé e kalẹ̀ fún títún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.” 8Àwọn àlùfáà fi ara mọ́ pé wọn kò nígbà owó kankan mọ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sì ni, wọn kò sì ní tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe mọ́ fúnra wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.