2 Ọba 12:11
2 Kings 12:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n bá ti pinnu iye rẹ̀, wọn a kó owó náà fún àwọn tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Pẹ̀lú u rẹ̀, wọ́n sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa; àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà àti àwọn olùkọ́lé.
2 Kings 12:11 in English
2 Kings 12:11 · Berean Standard Bible
Then they would put the counted money into the hands of those who supervised the work on the house of the LORD, who in turn would pay those doing the work—the carpenters, builders,
Context
9Jehoiada àlùfáà mú àpótí kan, ó sì lu ihò sí ìdérí rẹ̀. Ó gbé e sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ ní apá ọ̀tún bí ẹnìkan ti wọlé tí a kọ́ fún Olúwa. Àwọn àlùfáà tí ó ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé fi sínú àpótí náà gbogbo owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. 10Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ti rí wí pé owó púpọ̀ wà nínú àpótí, akọ̀wé ọba àti olórí àlùfáà yóò wá, wọ́n á ka owó náà tí wọ́n ti mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Wọn a sì kó o sínú àwọn àpò. 11Nígbà tí wọ́n bá ti pinnu iye rẹ̀, wọn a kó owó náà fún àwọn tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Pẹ̀lú u rẹ̀, wọ́n sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa; àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà àti àwọn olùkọ́lé. 12Àwọn ilé ńlá àti àwọn agékúta. Wọ́n ra igi gẹdú àti òkúta tí wọ́n tọ́jú fún tuntun ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe. Wọ́n tún ohun gbogbo tí wọ́n ná fún títún tẹmpili ṣe. 13Owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa kò jẹ́ níná fún ṣíṣe òpó fàdákà, ohun èlò ta fi ń fa ẹnu fìtílà, àwokòtò, ìpè, ohun èlò wúrà tàbí ohun èlò fàdákà kan fún ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.