2 Ọba 10:12
2 Kings 10:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jehu jáde lọ, ó sì lọ sí ọ̀kánkán Samaria. Ní Beti-Ekedi tí àwọn olùṣọ́-àgùntàn.
2 Kings 10:12 in English
2 Kings 10:12 · Berean Standard Bible
Then Jehu set out toward Samaria. At Beth-eked of the Shepherds,
Context
10Nígbà yìí, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí Olúwa ti sọ sí ilé Ahabu tí yóò kùnà. Olúwa ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Elijah.” 11Bẹ́ẹ̀ ni Jehu pa gbogbo ẹni tí ó kù Jesreeli ní ilé Ahabu, pẹ̀lúpẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin ìjòyè rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ àti àwọn àlùfáà rẹ̀, láì ku ẹni tí ó yọ nínú ewu fún un. 12Jehu jáde lọ, ó sì lọ sí ọ̀kánkán Samaria. Ní Beti-Ekedi tí àwọn olùṣọ́-àgùntàn. 13Jehu pàdé díẹ̀ lára àwọn ìbátan Ahasiah ọba Juda, ó sì béèrè, “Ta ni ẹ̀yin ń ṣe?”
Wọ́n wí pé, “Àwa jẹ́ ìbátan Ahasiah, àwa sì ti wá láti kí ìdílé ọba àti ti màmá ayaba.” 14“Mú wọn láààyè!” ó pàṣẹ. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mú wọn láààyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ẹ̀bá kọ̀nga Beti-Ekedi, ọkùnrin méjìlélógójì. Kò sì fi ẹnìkan sílẹ̀ láìkù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.