Native Bible

2 Kings 10:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà yìí, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí Olúwa ti sọ sí ilé Ahabu tí yóò kùnà. Olúwa ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Elijah.”

2 Kings 10:10 in English

2 Kings 10:10 · Berean Standard Bible

Know, then, that not a word the LORD has spoken against the house of Ahab will fail, for the LORD has done what He promised through His servant Elijah.”

Context

8Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé, ó sọ fún Jehu, “Wọ́n ti gbé orí àwọn ọmọ ọba náà wá.” Nígbà náà Jehu pàṣẹ, “Ẹ tò wọ́n ní òkìtì méjì ní àtiwọ ẹnu ibodè ìlú ńlá títí di òwúrọ̀.” 9Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Jehu jáde lọ. Ó dúró níwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin jẹ́ aláìjẹ̀bi. Èmi ni mo dìtẹ̀ sí ọ̀gá mi, tí mo sì pa á, ṣùgbọ́n ta ni ó pa gbogbo àwọn wọ̀nyí? 10Nígbà yìí, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí Olúwa ti sọ sí ilé Ahabu tí yóò kùnà. Olúwa ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Elijah.” 11Bẹ́ẹ̀ ni Jehu pa gbogbo ẹni tí ó kù Jesreeli ní ilé Ahabu, pẹ̀lúpẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin ìjòyè rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ àti àwọn àlùfáà rẹ̀, láì ku ẹni tí ó yọ nínú ewu fún un. 12Jehu jáde lọ, ó sì lọ sí ọ̀kánkán Samaria. Ní Beti-Ekedi tí àwọn olùṣọ́-àgùntàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.