2 Ọba 1:4
2 Kings 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà ohun tí Olúwa sọ ní èyí, ‘Ìwọ kò ní kúrò lórí ibùsùn tí o dùbúlẹ̀ lé. Dájúdájú ìwọ yóò kú!’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ.
2 Kings 1:4 in English
2 Kings 1:4 · Berean Standard Bible
Therefore this is what the LORD says: ‘You will not get up from the bed on which you are lying. You will surely die.’” So Elijah departed.
Context
2Nísinsin yìí Ahasiah ti ṣubú láàrín fèrèsé láti òkè yàrá rẹ̀ tí ó wà ní Samaria, ó sì fi ara pa. Ó sì rán oníṣẹ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni, bóyá èmi ó lè rí ìwòsàn ìfarapa yìí.” 3Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa wí fún Elijah ará Tiṣibi pé, “Lọ sókè kí o lọ bá ìránṣẹ́ ọba Samaria kí o sì béèrè lọ́wọ́ wọn, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli ni ẹ̀yìn fi jáde lọ ṣèwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu òrìṣà Ekroni?’ 4Nítorí náà ohun tí Olúwa sọ ní èyí, ‘Ìwọ kò ní kúrò lórí ibùsùn tí o dùbúlẹ̀ lé. Dájúdájú ìwọ yóò kú!’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ. 5Nígbà tí ìránṣẹ́ náà padà sí ọ̀dọ̀ ọba, ó béèrè ní ọwọ́ wọn pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi tètè padà wá?” 6Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin kan wá láti pàdé wa, ó sì wí fún wa pé, ‘Ẹ padà sí ọ̀dọ̀ ọba tí ó rán an yín kí ẹ sì wí fún un pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli ni o fi ń rán àwọn ènìyàn láti lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni? Nítorí náà ìwọ kò ní fi orí ibùsùn tí ìwọ dùbúlẹ̀ lé sílẹ̀. Láìsí àní àní ìwọ yóò kùú!” ’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.