2 Johanu 1:8
2 John 1:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ kíyèsára yín, kí ẹ má ba à sọ iṣẹ́ tí ẹ tí ṣe nù, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè rí èrè kíkún gbà.
2 John 1:8 in English
2 John 1:8 · Berean Standard Bible
Watch yourselves, so that you do not lose what we have worked for,* but that you may be fully rewarded.
Context
6Èyí sì ni ìfẹ́, pé, kí àwa máa rin nípa òfin rẹ̀, èyí ni òfin náà, àní bí ẹ ti gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé, kí ẹ̀yin rìn nínú rẹ̀. 7Nítorí ẹlẹ́tàn púpọ̀ ti jáde wa sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá nínú ara. Èyí ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi. 8Ẹ kíyèsára yín, kí ẹ má ba à sọ iṣẹ́ tí ẹ tí ṣe nù, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè rí èrè kíkún gbà. 9Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń rú òfin tí kò si dúró nínú ẹ̀kọ́ Kristi, kò mọ Ọlọ́run. Ẹni tí ó bá dúró nínú ẹ̀kọ́, òun ni ó mọ Baba àti Ọmọ. 10Bí ẹnikẹ́ni bá tọ̀ yín wá, tí kò sì mu ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé, kí ẹ má sì ṣe kí i kú ààbọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.