Native Bible

2 John 1:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ẹlẹ́tàn púpọ̀ ti jáde wa sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá nínú ara. Èyí ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi.

2 John 1:7 in English

2 John 1:7 · Berean Standard Bible

For many deceivers have gone out into the world, refusing to confess the coming of Jesus Christ in the flesh. Any such person is the deceiver and the antichrist.

Context

5Ǹjẹ́ nísinsin yìí, mo bẹ̀ ọ́, obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe bí ẹni pé èmi ń kọ̀wé òfin tuntun kan sí ọ, bí kò ṣe èyí ti àwa tí ní ní àtètèkọ́ṣe, pé kí àwa fẹ́ràn ara wa. 6Èyí sì ni ìfẹ́, pé, kí àwa máa rin nípa òfin rẹ̀, èyí ni òfin náà, àní bí ẹ ti gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé, kí ẹ̀yin rìn nínú rẹ̀. 7Nítorí ẹlẹ́tàn púpọ̀ ti jáde wa sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá nínú ara. Èyí ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi. 8Ẹ kíyèsára yín, kí ẹ má ba à sọ iṣẹ́ tí ẹ tí ṣe nù, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè rí èrè kíkún gbà. 9Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń rú òfin tí kò si dúró nínú ẹ̀kọ́ Kristi, kò mọ Ọlọ́run. Ẹni tí ó bá dúró nínú ẹ̀kọ́, òun ni ó mọ Baba àti Ọmọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.