2 Kọrinti 8:7
2 Corinthians 8:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti pọ̀ lóhùn gbogbo, ní ìgbàgbọ́, àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀, àti nínú iṣẹ́ ìyìnrere gbogbo, àti ní ìfẹ́ yín sí wa, ẹ rí i wí pé ẹ̀yin pọ̀ sí i nínú ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí pẹ̀lú.
2 Corinthians 8:7 in English
2 Corinthians 8:7 · Berean Standard Bible
But just as you excel in everything—in faith, in speech, in knowledge, in complete earnestness, and in the love we inspired in you *—see that you also excel in this grace of giving.
Context
5Àti èyí, kì í ṣe bí àwa tí rò rí, ṣùgbọ́n wọ́n tètè kọ́ fi àwọn fúnra wọn fún Olúwa, àti fún wá, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run. 6Tó bẹ́ẹ̀ tí àwa fi gba Titu níyànjú pé, bí ó tí bẹ̀rẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì parí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí nínú yín pẹ̀lú. 7Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti pọ̀ lóhùn gbogbo, ní ìgbàgbọ́, àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀, àti nínú iṣẹ́ ìyìnrere gbogbo, àti ní ìfẹ́ yín sí wa, ẹ rí i wí pé ẹ̀yin pọ̀ sí i nínú ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí pẹ̀lú. 8Kì í ṣe nípa àṣẹ ni mo fi ń sọ ọ́, ṣùgbọ́n kí a lè rí ìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín pẹ̀lú, nípa iṣẹ́ ìyìnrere ẹlòmíràn. 9Nítorí ẹ̀yin mọ oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi, pé bí òun ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ rí ṣùgbọ́n nítorí yín ó di tálákà kí a lè sọ yín di ọlọ́rọ̀ nípa àìní rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.