Native Bible

2 Corinthians 8:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwa ń gbèrò ohun rere, kì í ṣe níwájú Olúwa nìkan, ṣùgbọ́n níwájú ènìyàn pẹ̀lú.

2 Corinthians 8:21 in English

2 Corinthians 8:21 · Berean Standard Bible

For we are taking great care to do what is right, not only in the eyes of the Lord, but also in the eyes of men.

Context

19Kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ẹni tí a tí yàn wá pẹ̀lú láti ọ̀dọ̀ ìjọ láti máa bá wa rìn kiri nínú ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ yìí, tí àwa ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀ fún ògo Olúwa àti ìmúra ìtara wa. 20Àwa ń yẹra fún èyí, kí ẹnikẹ́ni má ba à rí wí sí wa ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí tí àwa pín. 21Àwa ń gbèrò ohun rere, kì í ṣe níwájú Olúwa nìkan, ṣùgbọ́n níwájú ènìyàn pẹ̀lú. 22Àwa sì ti rán arákùnrin wa pẹ̀lú wọn, ẹni tí àwa rí dájú nígbà púpọ̀ pé ó ní ìtara nínú ohun púpọ̀, ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí ni ìtara rẹ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ìfọkàntán ńlá tí ó ní sí yín. 23Bí ẹnikẹ́ni bá béèrè ẹni tí Titu jẹ́, ẹlẹgbẹ́ àti olùbáṣiṣẹ́ mi ni, nítorí yín; tàbí ní ti àwọn arákùnrin wa ni ẹnikẹ́ni ń béèrè, ìránṣẹ́ ìjọ ni wọ́n jẹ́, àti ògo Kristi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.