Native Bible

2 Corinthians 8:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní àkókò yìí, pé kí àníṣẹ́kù yín lè ṣe déédé àìní wọn, kí àníṣẹ́kù tiwọn pẹ̀lú ba à lè ṣe déédé àìní yín, kí ìmúdọ́gba ba à lè wà.

2 Corinthians 8:14 in English

2 Corinthians 8:14 · Berean Standard Bible

At the present time, your surplus will meet their need, so that in turn their surplus will meet your need. Then there will be equality.

Context

12Nítorí bí ìpinnu bá wà ṣáájú, ó jásí ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ènìyàn bá ní, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní. 13Nítorí èmi kò fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn wà ní ìrọ̀rùn, kí ó sì jẹ́ ìpọ́njú fún yín, ṣùgbọ́n pé nípa mímú dọ́gba. 14Ní àkókò yìí, pé kí àníṣẹ́kù yín lè ṣe déédé àìní wọn, kí àníṣẹ́kù tiwọn pẹ̀lú ba à lè ṣe déédé àìní yín, kí ìmúdọ́gba ba à lè wà. 15Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù.” 16Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fi ìtara àníyàn kan náà yìí sí ọkàn Titu fún yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.