2 Kọrinti 6:10
2 Corinthians 6:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí tálákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo.
2 Corinthians 6:10 in English
2 Corinthians 6:10 · Berean Standard Bible
sorrowful, yet always rejoicing; poor, yet making many rich; having nothing, and yet possessing everything.
Context
8Nípa ọlá àti ẹ̀gàn, nípa ìyìn búburú àti ìyìnrere: bí ẹlẹ́tàn, ṣùgbọ́n a jásí olóòtítọ́, 9bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú; bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a ṣì wà láààyè; bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá, 10bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí tálákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo. 11Ẹ̀yin ará Kọrinti, a ti bá yín sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀, a ṣí ọkàn wa páyà sí yín. 12Àwa kò fa ìfẹ́ wa sẹ́yìn fún yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin fa ìfẹ́ yín sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ wa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.