2 Kọrinti 5:2
2 Corinthians 5:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá.
2 Corinthians 5:2 in English
2 Corinthians 5:2 · Berean Standard Bible
For in this tent we groan, longing to be clothed with our heavenly dwelling,
Context
1Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run. 2Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá. 3Bí ó bá ṣe pé a ti fi wọ̀ wá, a kì yóò bá wa ní ìhòhò. 4Nítorí àwa tí a ń bẹ nínú àgọ́ yìí ń kérora nítòótọ́, kì í ṣe nítorí tí àwa fẹ́ jẹ́ aláìwọṣọ, ṣùgbọ́n pé a ó wọ̀ wá ní aṣọ sí i, kí ìyè ba à lè gbé ara kíkú mì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.