2 Kọrinti 2:7
2 Corinthians 2:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ìbá kúkú dáríjì í, kí ẹ sí tù ú nínú ní gbogbo ọ̀nà, kí ìbànújẹ́ má bà á bo irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀.
2 Corinthians 2:7 in English
2 Corinthians 2:7 · Berean Standard Bible
So instead, you ought to forgive and comfort him, so that he will not be overwhelmed by excessive sorrow.
Context
5Bí ẹnikẹ́ni bá fa ohun ìbànújẹ́ kì í ṣe èmi ni ó bà nínú jẹ́, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnra yín, níwọ̀n ìyówù kí ó jẹ́; n kò fẹ́ sọ ọ́ lọ́nà líle jù. 6Ìyà náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fi jẹ́ irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tó fún un. 7Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ìbá kúkú dáríjì í, kí ẹ sí tù ú nínú ní gbogbo ọ̀nà, kí ìbànújẹ́ má bà á bo irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀. 8Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìdánilójú ìfẹ́ yín hàn sí irú ẹni náà. 9Ìdí tí mo ṣe kọ̀wé ni kí èmi ba à lè rí ẹ̀rí dìímú nípa ìgbọ́ràn yín nínú ohun gbogbo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.