2 Kọrinti 13:5
2 Corinthians 13:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa dán ara yín wò. Tàbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ ara yín pé Jesu Kristi wá nínú yín? Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù.
2 Corinthians 13:5 in English
2 Corinthians 13:5 · Berean Standard Bible
Examine yourselves to see whether you are in the faith; test yourselves. Can’t you see for yourselves that Jesus Christ is in you—unless you actually fail the test?
Context
3Níwọ́n bí ẹ̀yin tí ń wá àmì Kristi ti ń sọ̀rọ̀ nínú mi, ẹni tí kì í ṣe àìlera sí yin, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ agbára nínú yín. 4Nítorí pé a kàn án mọ́ àgbélébùú nípa àìlera, ṣùgbọ́n òun wà láààyè nípa agbára Ọlọ́run. Nítorí àwa pẹ̀lú jásí aláìlera nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run sí yín. 5Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa dán ara yín wò. Tàbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ ara yín pé Jesu Kristi wá nínú yín? Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù. 6Ṣùgbọ́n mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, àwa kì í ṣe àwọn tí a tanù. 7Ǹjẹ́ àwa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí kí àwa lè farahàn bí àwọn ti ó tayọ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè máa ṣe èyí tí ó dára bí àwa tilẹ̀ dàbí àwọn tí a tanù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.