Native Bible

2 Corinthians 13:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Níwọ́n bí ẹ̀yin tí ń wá àmì Kristi ti ń sọ̀rọ̀ nínú mi, ẹni tí kì í ṣe àìlera sí yin, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ agbára nínú yín.

2 Corinthians 13:3 in English

2 Corinthians 13:3 · Berean Standard Bible

since you are demanding proof that Christ is speaking through me. He is not weak in dealing with you, but is powerful among you.

Context

1Èyí ni ó dí ìgbà kẹta tí èmi ń tọ̀ yín wá. Ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó fi ìdí ọ̀rọ̀ gbogbo múlẹ̀. 2Mo ti sọ fún yín ṣáájú, mo sì ń sọ fún yín tẹ́lẹ̀, bí ẹni pé mo wà pẹ̀lú yín nígbà kejì, àti bí èmi kò ti sí lọ́dọ̀ yín ní ìsinsin yìí, mo kọ̀wé sí àwọn tí ó ti ṣẹ̀ náà, àti sí gbogbo àwọn ẹlòmíràn, pé bí mo bá tún padà wá, èmi kì yóò dá wọn sí. 3Níwọ́n bí ẹ̀yin tí ń wá àmì Kristi ti ń sọ̀rọ̀ nínú mi, ẹni tí kì í ṣe àìlera sí yin, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ agbára nínú yín. 4Nítorí pé a kàn án mọ́ àgbélébùú nípa àìlera, ṣùgbọ́n òun wà láààyè nípa agbára Ọlọ́run. Nítorí àwa pẹ̀lú jásí aláìlera nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run sí yín. 5Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa dán ara yín wò. Tàbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ ara yín pé Jesu Kristi wá nínú yín? Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.