Native Bible

2 Corinthians 11:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ẹ̀yin fi inú dídùn gba àwọn òmùgọ̀ nígbà tí ẹ̀yin tìkára yín jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

2 Corinthians 11:19 in English

2 Corinthians 11:19 · Berean Standard Bible

For you gladly tolerate fools, since you are so wise.

Context

17Ohun tí èmi ń sọ, èmi kò sọ ọ́ nípa ti Olúwa, ṣùgbọ́n bí òmùgọ̀ nínú ìgbẹ́kẹ̀lé ìṣògo yìí. 18Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ni ó ń ṣògo nípa ti ara, èmi ó ṣògo pẹ̀lú. 19Nítorí ẹ̀yin fi inú dídùn gba àwọn òmùgọ̀ nígbà tí ẹ̀yin tìkára yín jẹ́ ọlọ́gbọ́n. 20Nítorí ẹ̀yin faradà á bí ẹnìkan bá sọ yín dí òǹdè, bí ẹnìkan bá jẹ́ yín run, bí ẹnìkan bá gbà lọ́wọ́ yín, bí ẹnìkan bá gbé ara rẹ̀ ga, bí ẹnìkan bá gbá yín lójú. 21Èmi ń wí lọ́nà ẹ̀gàn, bí ẹni pé àwa jẹ́ aláìlera! Ṣùgbọ́n nínú ohunkóhun tí ẹnìkan ti ní ìgboyà, èmi ń sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èmi ní ìgboyà pẹ̀lú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.