2 Kọrinti 10:3
2 Corinthians 10:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé, bí àwa tilẹ̀ n gbé nínú ayé, ṣùgbọ́n àwa kò jagun nípa ti ara.
2 Corinthians 10:3 in English
2 Corinthians 10:3 · Berean Standard Bible
For though we live in the flesh, we do not wage war according to the flesh.
Context
1Ṣùgbọ́n èmi Paulu fúnra mi fi inú tútù àti ìwà pẹ̀lẹ́ Kristi bẹ̀ yín, èmi ẹni ìrẹ̀lẹ̀ lójú yín nígbà tí mo wà láàrín yín, ṣùgbọ́n nígbà tí èmi kò sí, mo di ẹni ìgboyà sí yín. 2Ṣùgbọ́n èmi bẹ̀ yín pé nígbà tí mo wà láàrín yín, kí èmi ba à lè lo ìgboyà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé náà, eléyìí tí mo ti fọkàn sí láti fi dojúkọ àwọn kan, ti ń funra sí wa bí ẹni tí ń rìn nípa ìlànà ti ayé yìí. 3Nítorí pé, bí àwa tilẹ̀ n gbé nínú ayé, ṣùgbọ́n àwa kò jagun nípa ti ara. 4Nítorí ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n ó lágbára nínú Ọlọ́run láti wó ibi gíga palẹ̀. 5Àwa ń sọ gbogbo èrò àti gbogbo ohun gíga ti ń gbe ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ́run kalẹ̀, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbèkùn wá sí ìtẹríba fún Kristi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.