Native Bible

2 Corinthians 10:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, èyí nì, lórí iṣẹ́ ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí ààlà wa, àwa ó dí gbígbéga lọ́dọ̀ yín sí i lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

2 Corinthians 10:15 in English

2 Corinthians 10:15 · Berean Standard Bible

Neither do we boast beyond our limits in the labors of others. But we hope that as your faith increases, our area of influence among you will greatly increase as well,

Context

13Ṣùgbọ́n àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, ṣùgbọ́n nípa ààlà ìwọ̀n tí Ọlọ́run ti pín fún wa, èyí tí ó mú kí ó ṣe é ṣe láti dé ọ̀dọ̀ yín. 14Nítorí àwa kò nawọ́ wa rékọjá rárá, bí ẹni pé àwa kò dé ọ̀dọ̀ yín: nítorí àwa tilẹ̀ dé ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú nínú ìyìnrere Kristi. 15Àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, èyí nì, lórí iṣẹ́ ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí ààlà wa, àwa ó dí gbígbéga lọ́dọ̀ yín sí i lọ́pọ̀lọ́pọ̀. 16Kí a bá à lè wàásù ìyìnrere ní àwọn ìlú tí ń bẹ níwájú yín, kí a má sì ṣògo nínú ààlà ẹlòmíràn nípa ohun tí ó wà ní àrọ́wọ́tó. 17“Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.