2 Kọrinti 10:14
2 Corinthians 10:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí àwa kò nawọ́ wa rékọjá rárá, bí ẹni pé àwa kò dé ọ̀dọ̀ yín: nítorí àwa tilẹ̀ dé ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú nínú ìyìnrere Kristi.
2 Corinthians 10:14 in English
2 Corinthians 10:14 · Berean Standard Bible
We are not overstepping our bounds, as if we had not come to you. Indeed, we were the first to reach you with the gospel of Christ.
Context
12Nítorí pé àwa kò dáṣà láti ka ara wa mọ́, tàbí láti fi ara wa wé àwọn mìíràn nínú wọn tí ń yin ara wọn; ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn jẹ́ aláìlóye bí wọn ti ń fi ara wọn díwọ̀n ara wọ́n, tí wọ́n sì ń fi ara wọn wé ara wọn. 13Ṣùgbọ́n àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, ṣùgbọ́n nípa ààlà ìwọ̀n tí Ọlọ́run ti pín fún wa, èyí tí ó mú kí ó ṣe é ṣe láti dé ọ̀dọ̀ yín. 14Nítorí àwa kò nawọ́ wa rékọjá rárá, bí ẹni pé àwa kò dé ọ̀dọ̀ yín: nítorí àwa tilẹ̀ dé ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú nínú ìyìnrere Kristi. 15Àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, èyí nì, lórí iṣẹ́ ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí ààlà wa, àwa ó dí gbígbéga lọ́dọ̀ yín sí i lọ́pọ̀lọ́pọ̀. 16Kí a bá à lè wàásù ìyìnrere ní àwọn ìlú tí ń bẹ níwájú yín, kí a má sì ṣògo nínú ààlà ẹlòmíràn nípa ohun tí ó wà ní àrọ́wọ́tó.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.