2 Kronika 9:8
2 Chronicles 9:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìyìn ló yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn nínú rẹ tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ láti jẹ ọba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run rẹ fún Israẹli láti fi ìdí wọn kalẹ̀ láéláé, ó sì ti fi ọ́ ṣe ọba lórí wọn, láti ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́.”
2 Chronicles 9:8 in English
2 Chronicles 9:8 · Berean Standard Bible
Blessed be the LORD your God, who has delighted in you to set you on His throne to be king for the LORD your God. Because your God loved Israel enough to establish them forever, He has made you king over them to carry out justice and righteousness.”
Context
6Ṣùgbọ́n èmi kò gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́ àyàfi ìgbà tí mó dé ibí tí mo sì ri pẹ̀lú ojú mi. Nítòótọ́, kì í tilẹ̀ ṣe ìdájọ́ ìdajì títóbi ọgbọ́n rẹ ní a sọ fún mi: ìwọ ti tàn kọjá òkìkí tí mo gbọ́. 7Báwo ni inú àwọn ọkùnrin rẹ ìbá ṣe dùn tó! Báwo ní dídùn inú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí n dúró nígbà gbogbo níwájú rẹ láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ! 8Ìyìn ló yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn nínú rẹ tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ láti jẹ ọba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run rẹ fún Israẹli láti fi ìdí wọn kalẹ̀ láéláé, ó sì ti fi ọ́ ṣe ọba lórí wọn, láti ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́.” 9Nígbà náà ni ó sì fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye tùràrí, àti òkúta iyebíye. Kò sì tí ì sí irú tùràrí yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ayaba Ṣeba fi fún ọba Solomoni. 10Àwọn ènìyàn Hiramu àti àwọn ọkùnrin Solomoni gbé wúrà wá láti Ofiri, wọ́n sì tún gbé igi algumu pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.