Native Bible

2 Chronicles 9:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ, òtítọ́ ni.

2 Chronicles 9:5 in English

2 Chronicles 9:5 · Berean Standard Bible

She said to the king, “The report I heard in my own country about your words * and wisdom is true.

Context

3Nígbà tí ayaba Ṣeba rí ọgbọ́n Solomoni àti pẹ̀lú ilé tí ó ti kọ́, 4oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì rẹ̀, àti ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti dídúró àwọn ìránṣẹ́ nínú aṣọ wọn, àti àwọn agbọ́tí nínú aṣọ wọn àti ẹbọ sísun tí ó ṣe ní ilé Olúwa, ó sì dá a lágara fún ìyàlẹ́nu. 5Ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ, òtítọ́ ni. 6Ṣùgbọ́n èmi kò gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́ àyàfi ìgbà tí mó dé ibí tí mo sì ri pẹ̀lú ojú mi. Nítòótọ́, kì í tilẹ̀ ṣe ìdájọ́ ìdajì títóbi ọgbọ́n rẹ ní a sọ fún mi: ìwọ ti tàn kọjá òkìkí tí mo gbọ́. 7Báwo ni inú àwọn ọkùnrin rẹ ìbá ṣe dùn tó! Báwo ní dídùn inú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí n dúró nígbà gbogbo níwájú rẹ láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.