Native Bible

2 Chronicles 7:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí iná tí ó ń sọ̀kalẹ̀ àti ògo Olúwa lórí ilé Olúwa náà, wọ́n sì kúnlẹ̀ lórí eékún wọn pẹ̀lú ojú ni dídàbolẹ̀, wọ́n sì sin Olúwa, wọ́n sì fi ìyìn fún Olúwa wí pé, “Nítorí tí ó dára; àánú rẹ̀ sì dúró títí láéláé.”

2 Chronicles 7:3 in English

2 Chronicles 7:3 · Berean Standard Bible

When all the Israelites saw the fire coming down and the glory of the LORD above the temple, they bowed down on the pavement with their faces to the ground, and they worshiped and gave thanks to the LORD: “For He is good; His loving devotion endures forever.”

Context

1Nígbà tí Solomoni sì ti parí àdúrà, iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó ẹbọ sísun àti ẹbọ, ògo Ọlọ́run sì kún ilé Olúwa. 2Àwọn àlùfáà kò sì le wo ilé Olúwa náà nítorí pé ògo Olúwa kún un. 3Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí iná tí ó ń sọ̀kalẹ̀ àti ògo Olúwa lórí ilé Olúwa náà, wọ́n sì kúnlẹ̀ lórí eékún wọn pẹ̀lú ojú ni dídàbolẹ̀, wọ́n sì sin Olúwa, wọ́n sì fi ìyìn fún Olúwa wí pé, “Nítorí tí ó dára; àánú rẹ̀ sì dúró títí láéláé.” 4Nígbà náà ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn sì rú ẹbọ níwájú Olúwa. 5Ọba Solomoni sì rú ẹbọ ti ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000), orí màlúù àti àgùntàn àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn àti ẹranko. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn ya ilé Ọlọ́run sí mímọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.