Native Bible

2 Chronicles 36:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi ọba Persia, kí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a tẹnu Jeremiah sọ bá à le ṣẹ pé, Olúwa run ẹ̀mí Kirusi ọba Persia láti ṣe ìkéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì kọ ọ́ sínú ìwé pẹ̀lú.

2 Chronicles 36:22 in English

2 Chronicles 36:22 · Berean Standard Bible

In the first year of Cyrus king of Persia, to fulfill the word of the LORD spoken through Jeremiah, the LORD stirred the spirit of Cyrus king of Persia to send a proclamation throughout his kingdom and to put it in writing as follows:

Context

20Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Babeli àwọn tí ó rí ibi sá kúrò lẹ́nu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Persia fi gba agbára. 21Ilẹ̀ náà sì gbádùn ìsinmi rẹ̀, ní gbogbo ìgbà ìdahoro, òun sì ń sinmi títí àádọ́rin ọdún fi pé ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ láti ẹnu Jeremiah. 22Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi ọba Persia, kí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a tẹnu Jeremiah sọ bá à le ṣẹ pé, Olúwa run ẹ̀mí Kirusi ọba Persia láti ṣe ìkéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì kọ ọ́ sínú ìwé pẹ̀lú. 23“Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia sọ wí pé: “ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mí ní gbogbo ìjọba ayé yìí, ó sì ti yàn mí láti kọ́ ilé Olúwa fún òun ní Jerusalẹmu ti Juda. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín le gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀; kí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ kí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.