2 Kronika 36:2
2 Chronicles 36:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jehoahasi sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta.
2 Chronicles 36:2 in English
2 Chronicles 36:2 · Berean Standard Bible
Jehoahaz * was twenty-three years old when he became king, and he reigned in Jerusalem three months.
Context
1Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jehoahasi ọmọ Josiah wọn sì fi jẹ ọba ní Jerusalẹmu ni ipò baba rẹ̀. 2Jehoahasi sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. 3Ọba Ejibiti yọ kúrò lórí ìtẹ́ ní Jerusalẹmu, ó sì bù fún un lórí Juda, ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà àti tálẹ́ǹtì wúrà kan. 4Ọba Ejibiti sì mú Eliakimu, arákùnrin Joahasi, jẹ ọba lórí Juda àti Jerusalẹmu, ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu, ṣùgbọ́n Neko mú Joahasi arákùnrin Eliakimu lọ sí Ejibiti.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.