2 Kronika 34:14
2 Chronicles 34:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n mú owó náà tí wọ́n mú wá sí ilé Olúwa, Hilkiah àlùfáà sì rí ìwé òfin Olúwa tí a ti fi fún un láti ọwọ́ Mose.
2 Chronicles 34:14 in English
2 Chronicles 34:14 · Berean Standard Bible
While they were bringing out the money that had been taken into the house of the LORD, Hilkiah the priest found the Book of the Law of the LORD written by * Moses.
Context
12Àwọn ọkùnrin náà ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú òtítọ́, láti darí wọn ní Jahati àti Obadiah, àwọn ọmọ Lefi láti Merari, àti Sekariah àti Meṣullamu, sọ̀kalẹ̀ láti Kohati àwọn ọmọ Lefi gbogbo tí ó ní ọgbọ̀n ohun èlò orin. 13Wọ́n sì ní olórí àwọn aláàárù àti àwọn alábojútó gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ láti ibi iṣẹ́ sí ibi iṣẹ́, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Lefi sì ní akọ̀wé, olùtọ́jú àti olùṣọ́nà. 14Nígbà tí wọ́n mú owó náà tí wọ́n mú wá sí ilé Olúwa, Hilkiah àlùfáà sì rí ìwé òfin Olúwa tí a ti fi fún un láti ọwọ́ Mose. 15Hilkiah sì wí fún Ṣafani akọ̀wé pé, “Èmi ti rí ìwé òfin nínú ilé Olúwa.” Ó sì fi fún Ṣafani. 16Nígbà náà Ṣafani sì mú ìwé náà lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ó sì ròyìn fún un. “Àwọn ìjòyè rẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan tí a ti fi lé wọn lọ́wọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.