2 Kronika 32:23
2 Chronicles 32:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀pọ̀ mú ọrẹ wá sí Jerusalẹmu fún Olúwa àti àwọn ẹ̀bùn iyebíye fún Hesekiah ọba Juda. Ó sì gbéga lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́yìn náà.
2 Chronicles 32:23 in English
2 Chronicles 32:23 · Berean Standard Bible
Many brought offerings to Jerusalem for the LORD and valuable gifts for Hezekiah king of Judah, and from then on he was exalted in the eyes of all nations.
Context
21Olúwa sì ran angẹli tí ó pa gbogbo àwọn ọmọ-ogun àti àwọn adarí àti àwọn ìjòyè tí ó wà nínú àgọ́ ọba Asiria run. Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí ilẹ̀ rẹ̀ ní ìtìjú. Nígbà tí ó sì lọ sínú ilé ọlọ́run rẹ̀, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà. 22Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yọ Hesekiah àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu kúrò lọ́wọ́ Sennakeribu ọba Asiria àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn mìíràn. Ó tọ́jú wọn ní gbogbo ọ̀nà. 23Ọ̀pọ̀ mú ọrẹ wá sí Jerusalẹmu fún Olúwa àti àwọn ẹ̀bùn iyebíye fún Hesekiah ọba Juda. Ó sì gbéga lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́yìn náà. 24Ní ọjọ́ wọ́n nì Hesekiah ṣe àárẹ̀, ó sì dójú ikú. Ó gbàdúrà sí Olúwa tí ó dá a lóhùn, tí ó sì fún un ní àmì àgbàyanu. 25Ṣùgbọ́n ọkàn Hesekiah ṣe ìgbéraga, kò sì kọbi ara sí i inú rere tí a fihàn án. Nítorí náà, ìbínú Olúwa wà lórí rẹ̀ àti lórí Juda àti Jerusalẹmu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.