2 Kronika 28:22
2 Chronicles 28:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní àkókò ìpọ́njú rẹ̀ ọba Ahasi sì di aláìṣòótọ́ sí Olúwa.
2 Chronicles 28:22 in English
2 Chronicles 28:22 · Berean Standard Bible
In the time of his distress, King Ahaz became even more unfaithful to the LORD.
Context
20Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fún ní ìpọ́njú dípò ìrànlọ́wọ́. 21Ahasi mú díẹ̀ nínú ìní ilé Olúwa àti láti ilé ọba àti láti ọ̀dọ̀ ọba ó sì fi wọ́n fún ọba Asiria: ṣùgbọ́n èyí kò ràn wọ́n lọ́wọ́. 22Ní àkókò ìpọ́njú rẹ̀ ọba Ahasi sì di aláìṣòótọ́ sí Olúwa. 23Ó sì rú ẹbọ sí òrìṣà àwọn Damasku, ẹni tí ó ṣẹ́gun wọn, nítorí ó rò wí pé, “Nítorí àwọn òrìṣà àwọn ọba Siria ti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọn kí ó bà lè ràn mí lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n àwọn ni ìparun rẹ̀ àti ti gbogbo Israẹli. 24Ahasi sì kó gbogbo ohun èlò láti ilé Olúwa jọ ó sì kó wọn lọ. Ó sì ti ìlẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tẹ́ pẹpẹ fún ara rẹ̀ ní gbogbo igun Jerusalẹmu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.