Native Bible

2 Chronicles 26:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà gbogbo ènìyàn Juda mú Ussiah, ẹni tí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún wọ́n sì fi jẹ ọba ní ipò baba rẹ̀ Amasiah.

2 Chronicles 26:1 in English

2 Chronicles 26:1 · Berean Standard Bible

All the people of Judah took Uzziah,* who was sixteen years old, and made him king in place of his father Amaziah.

Context

1Nígbà náà gbogbo ènìyàn Juda mú Ussiah, ẹni tí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún wọ́n sì fi jẹ ọba ní ipò baba rẹ̀ Amasiah. 2Òun ni ẹni náà tí ó tún Elati kọ́, ó sì mú padà sí Juda lẹ́yìn ìgbà tí Amasiah ọba ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. 3Ussiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìléláàádọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jekoliah; ó sì wá láti Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.