Native Bible

2 Chronicles 25:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọba kó gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò tí wọ́n rí ni ilé Ọlọ́run tí ọ́ wà ní àbojútó Obedi-Edomu, lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣúra ààfin àti àwọn ògo pẹ̀lú, ó sì padà lọ sí Samaria.

2 Chronicles 25:24 in English

2 Chronicles 25:24 · Berean Standard Bible

He took all the gold and silver and all the articles found in the house of God with Obed-edom and in the treasuries of the royal palace, as well as some hostages. Then he returned to Samaria.

Context

22Àwọn ọmọ Israẹli da Juda rú, gbogbo olúkúlùkù ènìyàn sì sálọ sí ìlú rẹ̀. 23Jehoaṣi ọba Israẹli fi agbára mú Amasiah ọba Juda, ọmọ Joaṣi ọmọ Ahasiah ní Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà Joaṣi mú u wá sí Jerusalẹmu. Ó sì wó ògiri Jerusalẹmu lulẹ̀ láti ẹnu-ọ̀nà Efraimu sí igun ẹnu-ọ̀nà apá kan títí ń lọ sí irinwó (400) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. 24Ọba kó gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò tí wọ́n rí ni ilé Ọlọ́run tí ọ́ wà ní àbojútó Obedi-Edomu, lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣúra ààfin àti àwọn ògo pẹ̀lú, ó sì padà lọ sí Samaria. 25Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israẹli. 26Fún ti iṣẹ́ mìíràn ti ìjọba Amasiah láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé àwọn ọba Juda àti Israẹli?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.