Native Bible

2 Chronicles 25:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jehoaṣi ọba Israẹli fi agbára mú Amasiah ọba Juda, ọmọ Joaṣi ọmọ Ahasiah ní Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà Joaṣi mú u wá sí Jerusalẹmu. Ó sì wó ògiri Jerusalẹmu lulẹ̀ láti ẹnu-ọ̀nà Efraimu sí igun ẹnu-ọ̀nà apá kan títí ń lọ sí irinwó (400) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn.

2 Chronicles 25:23 in English

2 Chronicles 25:23 · Berean Standard Bible

There at Beth-shemesh, Jehoash king of Israel captured Amaziah king of Judah, the son of Joash, the son of Jehoahaz.* Then Jehoash brought him to Jerusalem and broke down the wall of Jerusalem from the Ephraim Gate to the Corner Gate—a section of four hundred cubits.*

Context

21Bẹ́ẹ̀ ni Jehoaṣi, ọba Israẹli: òun àti Amasiah ọba Juda dojúkọ ara wọn ní Beti-Ṣemeṣi ní Juda. 22Àwọn ọmọ Israẹli da Juda rú, gbogbo olúkúlùkù ènìyàn sì sálọ sí ìlú rẹ̀. 23Jehoaṣi ọba Israẹli fi agbára mú Amasiah ọba Juda, ọmọ Joaṣi ọmọ Ahasiah ní Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà Joaṣi mú u wá sí Jerusalẹmu. Ó sì wó ògiri Jerusalẹmu lulẹ̀ láti ẹnu-ọ̀nà Efraimu sí igun ẹnu-ọ̀nà apá kan títí ń lọ sí irinwó (400) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. 24Ọba kó gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò tí wọ́n rí ni ilé Ọlọ́run tí ọ́ wà ní àbojútó Obedi-Edomu, lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣúra ààfin àti àwọn ògo pẹ̀lú, ó sì padà lọ sí Samaria. 25Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.