Native Bible

2 Chronicles 25:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Amasiah, bí ó tì wù kí ó rí kò tẹ́tí nítorí Ọlọ́run ṣe é kí ó lè gbé wọn lé Jehoaṣi lọ́wọ́: nítorí wọ́n wá àwọn ọlọ́run Edomu.

2 Chronicles 25:20 in English

2 Chronicles 25:20 · Berean Standard Bible

But Amaziah would not listen, for this had come from God in order to deliver them into the hand of Jehoash, because they had sought the gods of Edom.

Context

18Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Israẹli fèsì padà sí Amasiah ọba Juda pé, “Koríko kékeré kan ní Lebanoni rán iṣẹ́ sí igi kedari ní Lebanoni, fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwó. Nígbà náà, ẹhànnà ẹranko ènìyàn ni Lebanoni wá, ó sì tẹ òṣùṣú náà lábẹ́ ẹsẹ̀. 19Ìwọ wí fún ara à rẹ wí pé, ìwọ ti ṣẹ́gun Edomu àti nísinsin yìí ìwọ ní ìhàlẹ̀ àti ìgbéraga. Ṣùgbọ́n dúró ní ilé! Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń wá wàhálà tí o sì fi ń fa ìṣubú rẹ àti ti Juda pẹ̀lú?” 20Amasiah, bí ó tì wù kí ó rí kò tẹ́tí nítorí Ọlọ́run ṣe é kí ó lè gbé wọn lé Jehoaṣi lọ́wọ́: nítorí wọ́n wá àwọn ọlọ́run Edomu. 21Bẹ́ẹ̀ ni Jehoaṣi, ọba Israẹli: òun àti Amasiah ọba Juda dojúkọ ara wọn ní Beti-Ṣemeṣi ní Juda. 22Àwọn ọmọ Israẹli da Juda rú, gbogbo olúkúlùkù ènìyàn sì sálọ sí ìlú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.