Native Bible

2 Chronicles 25:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ wí fún ara à rẹ wí pé, ìwọ ti ṣẹ́gun Edomu àti nísinsin yìí ìwọ ní ìhàlẹ̀ àti ìgbéraga. Ṣùgbọ́n dúró ní ilé! Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń wá wàhálà tí o sì fi ń fa ìṣubú rẹ àti ti Juda pẹ̀lú?”

2 Chronicles 25:19 in English

2 Chronicles 25:19 · Berean Standard Bible

You have said, ‘Look, I have defeated Edom,’ and your heart has become proud and boastful. Now stay at home. Why should you stir up trouble so that you fall—you and Judah with you?”

Context

17Lẹ́yìn tí Amasiah ọba Juda ti béèrè lọ́wọ́ àwọn olùdámọ̀ràn, ó rán ìpèníjà yìí sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọmọ Jehu, ọba Israẹli pé, “Wá bá mi lójúkojú.” 18Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Israẹli fèsì padà sí Amasiah ọba Juda pé, “Koríko kékeré kan ní Lebanoni rán iṣẹ́ sí igi kedari ní Lebanoni, fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwó. Nígbà náà, ẹhànnà ẹranko ènìyàn ni Lebanoni wá, ó sì tẹ òṣùṣú náà lábẹ́ ẹsẹ̀. 19Ìwọ wí fún ara à rẹ wí pé, ìwọ ti ṣẹ́gun Edomu àti nísinsin yìí ìwọ ní ìhàlẹ̀ àti ìgbéraga. Ṣùgbọ́n dúró ní ilé! Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń wá wàhálà tí o sì fi ń fa ìṣubú rẹ àti ti Juda pẹ̀lú?” 20Amasiah, bí ó tì wù kí ó rí kò tẹ́tí nítorí Ọlọ́run ṣe é kí ó lè gbé wọn lé Jehoaṣi lọ́wọ́: nítorí wọ́n wá àwọn ọlọ́run Edomu. 21Bẹ́ẹ̀ ni Jehoaṣi, ọba Israẹli: òun àti Amasiah ọba Juda dojúkọ ara wọn ní Beti-Ṣemeṣi ní Juda.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.