Native Bible

2 Chronicles 24:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn ikú Jehoiada, àwọn oníṣẹ́ Juda wá láti fi ìforíbalẹ̀ wọn hàn sí ọba. Ó sì fèsì sí wọn.

2 Chronicles 24:17 in English

2 Chronicles 24:17 · Berean Standard Bible

After the death of Jehoiada, however, the officials of Judah came and paid homage to the king, and he listened to them.

Context

15Ṣùgbọ́n Jehoiada di arúgbó, ó sì kún fún ọjọ́, ó sì kú, ẹni àádóje ọdún ni nígbà tí ó kú. 16Wọ́n sì sin ín ní ìlú Dafidi pẹ̀lú àwọn ọba, nítorí tí ó ṣe rere ní Israẹli, àti sí Ọlọ́run àti sí ilé rẹ̀. 17Lẹ́yìn ikú Jehoiada, àwọn oníṣẹ́ Juda wá láti fi ìforíbalẹ̀ wọn hàn sí ọba. Ó sì fèsì sí wọn. 18Wọ́n pa ilé Olúwa tì, Ọlọ́run baba a wọn. Wọ́n sì ń sin àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yìí, ìbínú Ọlọ́run dé sórí Juda àti Jerusalẹmu. 19Bí ó ti wù kí ó rí, Olúwa rán àwọn wòlíì sí àwọn ènìyàn láti mú wọn padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, wọ́n jẹ́rìí nípa wọn, wọn kì yóò gbọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.