Native Bible

2 Chronicles 24:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì sin ín ní ìlú Dafidi pẹ̀lú àwọn ọba, nítorí tí ó ṣe rere ní Israẹli, àti sí Ọlọ́run àti sí ilé rẹ̀.

2 Chronicles 24:16 in English

2 Chronicles 24:16 · Berean Standard Bible

And Jehoiada was buried with the kings in the City of David, because he had done what was good in Israel for God and His temple.

Context

14Nígbà tí wọ́n sì parí rẹ̀ tán, wọ́n mú owó ìyókù wá sí iwájú ọba àti Jehoiada, a sì fi ohun èlò fún ilé Olúwa, àní ohun èlò fún ìsìn àti fún ẹbọ pẹ̀lú ọpọ́n, àní ohun èlò wúrà àti fàdákà. Wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun ní ilé Olúwa nígbà gbogbo ní gbogbo ọjọ́ Jehoiada. 15Ṣùgbọ́n Jehoiada di arúgbó, ó sì kún fún ọjọ́, ó sì kú, ẹni àádóje ọdún ni nígbà tí ó kú. 16Wọ́n sì sin ín ní ìlú Dafidi pẹ̀lú àwọn ọba, nítorí tí ó ṣe rere ní Israẹli, àti sí Ọlọ́run àti sí ilé rẹ̀. 17Lẹ́yìn ikú Jehoiada, àwọn oníṣẹ́ Juda wá láti fi ìforíbalẹ̀ wọn hàn sí ọba. Ó sì fèsì sí wọn. 18Wọ́n pa ilé Olúwa tì, Ọlọ́run baba a wọn. Wọ́n sì ń sin àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yìí, ìbínú Ọlọ́run dé sórí Juda àti Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.